Nípa Olóyè Ifálérè Ọdẹ́gbọlá Ọdẹ́gbèmí

Abí Olóyè Ifálérè Ọdẹ́gbọlá Ọdẹ́gbèmí ní ọdún 1960 ní agbolé Alápẹ Agbeni, Ìbàdàn. Ó lọ sí ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ní Ẹlẹ́nusóńsó ní ìjọba ìbílẹ̀ Ìdó, Ìbàdàn. Ifá pè é padà wálé ní ìgbàtí ó wà bíi ìwé kejì alákọ́ọ́bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1970, ìgbà yìí ni ó bọ́ sí ilé ọ̀gá rẹ̀ Olóògbé Ọlájídé Àjàó, agbolé Ọmọ-Fọ̀kọ̀, Ìbàdàn. Bàbá yìí sósùn (ó kú) ní 1973, ó padà sí ọ̀dọ̀ bàbá rẹ̀ Àgbà-oyè Ọdẹ́gbọlá Àlàó, ó tún ń kọ́ ẹ̀kọ́ ifá rẹ̀ lọ. Bàbá rẹ̀ Àgbà-oyè Ọdẹ́gbọlá Àlàó di Àràbà ilẹ̀ Ìbàdàn ní 1977, ní ọdún yìí náà ni wọ́n fà á lé Olóyè Akin-adé Ayọ̀-adé Àwísẹ ilẹ̀ Ìbàdàn lónìí lọ́wọ́, tí ó sì kọ́ ẹ̀kọ́ ifá yìí di 1984 kí ó tó di ọ̀gá ararẹ̀ tí ó sì gba ìwúre. Olóyè Ifálérè ka ìwé ẹ̀kọ́ àgbà ní ààrín ọdún 1982 sí 1986 èyí tí ó fi jáde ìwé mẹ́wàá ní (Agbowó Study Centre U.I.) Olóyè Ifálérè ní ìyàwó, ó sì  bí ọmọ pẹ̀lú. Àgbà-oyè Ọdẹ́gbọlá Àlàó sósùn ní 1989. Olóyè Ifálérè jẹ akọ̀wé ẹgbẹ́ Akọrin Ìmọ́lẹ̀ Òsùpá Ọ̀sẹ́-méjì fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Olóyè Ifálérè bẹ̀rẹ̀ oyè jíjẹ̀ ní ọdún 1992 nígbà tí ó jẹ Ọ̀tún Olóògbé Akin-ọlá Akínlẹ́yẹ Àràbà ilẹ̀ Ìbàdàn ní 2002 si 2013 èyí tí Olóyè Ifálérè fi bẹ̀rẹ̀ oyè ilẹ̀ Ìbàdàn kí ó tó dí Akọ́dá Awo ilẹ̀ Ìbàdàn lónìí. Òhun ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó kọ “ÌWÉ MÍMỌ́ IFÁ: ÀDÌMÚLÀ OHÙN ẸNU OLÓDÙMARÈ” ní ọdún 2008. Kí Olódùmarè má jẹ̀ẹ́ kí ayé ó gba ògo ẹnìkankan wa. Ó sì tún kọ ìwé “ÌBÁGBÉPỌ̀ TỌKỌ TAYA” ní ọdún 2014, “ÌWÉ MÍMỌ́ IFÁ Ẹ̀SÌN ÀKỌ́DÁ OLÓDÙMARÈ” yìí ni ó jẹ́ ẹ̀kẹta, òmíràn tún ńbọ̀ lọ́nà pẹ̀lú àsẹ Olódùmarè. 

Àwọn Ipò tí ó ti dìmú

Olóyè Ifálérè jẹ́ Olórí Ẹgbẹ́ Ìfẹ́lólesẹ́ 1982 títí di 1998.

Akọ̀wé Akọrin Ìmọ́lẹ̀ Òsùpá Ọ̀sẹ́ Méjì Ìbàdàn 1981 títí di 1990.

Akọ̀wé Àjọ Àràbà ilẹ̀ Ìbàdàn 1993 títí di 2012

Akọ̀wé Ẹgbẹ́ Ifá Fẹ́mi Fẹrere 1996 títí di 2014.

Ọ̀tún Olóyè Akinọlá Akínlẹyẹ́ 1992,

1992 náà ni Olóyè Ifálérè bẹ̀rẹ̀ oyè ifá ní ilẹ̀ Ìbàdàn, èyí tí ó tò dé Àkọ́dá Awo ilẹ̀ Ìbàdàn lónìí. Award Peacemaker

 

Contact Address

Stay in Touch

Distributors Contacts

12, Falere Odegbola Street, Off Alakaso Road,

Omi-Adio, Ibadan, Ido LGA, Oyo State, Nigeria.

Phone No: +2348054009431, +2347034208381

Email: info@odegbolaifalere.com

Website: www.odegbolaifalere.com

=> OAJ Book shop Dugbe, Ibadan, Oyo State. +2349189747423

=> Otunba Lekan Ajirotutu, NTA Ch 10, Lagos State.

=> Tubosun Oladapo, Lagos Garage, Iwo Road, Ibadan, Oyo State.

=> Odusote Book Shop, Oke-Bola, Ibadan.

 

=> Deji Medubi, UNILAG, Lagos State.

=> Ejiodi Home of Tradition, Alade Near Moniya, Ibadan, Oyo State.

=> Dr. Adeola Faleye, OAU Ile-Ife, Osun State.

=> Dr. Abiodun Agboola, OAU Ile-Ife, Osun State.

=> OAU Bookshop, Ile-Ife, Osun State.

=> U.I Bookshop Ibadan, Oyo State. 

=> 13, Elebuibon Street, Osogbo, Osun State

Subscribe to our Newsletter

Navigation